Take a fresh look at your lifestyle.

Iná ọjà Maiduguri: Gómìnà Zulum kéde Mílíọ́nù Náírà kan fún owó ìtura pàjáwìrì

0 251

Gómìnà ìpinlẹ Bornu,Ọ̀jọ̀gbọ́n Babagana Umara Zulum ti kéde Bílíọ́nù kan Náírà fún iye owó ìtura pàjáwìrì láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tọ́rọ̀ kàn, kí wọ́n tó ṣe àgbéyẹ̀wò ọsẹ́ tí iná náà ṣe.

Agbẹnusọ Gómìnà, Malam Isa Gusau, nínú àlàyé kan tí ó ṣe ní ọjọ́ Àìkú, pé Zulum ṣe ìkéde yìí lẹ́yìn tí ó ti ṣe àbẹ̀wò sí ibùdó iná náà, tí ó sì da àwọn ọmọ ológun sí agbègbè náà fún àmójútó, kí wàhálà kankan máá baà bẹ́ sílẹ̀.

Gómìnà, tí ó ṣàpéjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ohun tó bani lọkan jẹ́, wá rọ àwọn ara ilu pè kí wọ́n fọkànbalẹ̀.

Gómìnà kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà, O sọ pe ìjọba ìpínlẹ̀ Bornu ti ṣetán láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti ṣe àtúnṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

 

Eyitayo Fauziat Oyetunji.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button