Take a fresh look at your lifestyle.

Ìbò Ọdún 2023: Olùdíje ipò Ààrẹ fún Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC, Bola Tinubu Gbóríyìn Fún Àjọ elétò Ìdìbò

0 218

Olùdíje fún ipo Ààrẹ labẹ asia Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC, Ọ̀gbẹ́ni Bọlá Tinubu ti gbóríyìn fun Àjọ Eleto Ìdìbò (INEC), fun irọwọrọsẹ Ìdìbò to ni àlàáfíà tí ó wáyé lónìí. Igboriyin naa wáyé nígbà tí ó dibo rẹ tán lónìí, ni Òpópónà Keffi Ikeja, ní Olú ìlú ìpínlẹ̀ Eko. Ó gbóríyìn fún àwọn Oludibo bi wọn ṣé tú yáyá tú yàyà láti dibo.

Nígbà ti ó n ba awọn Oniròyìn sọrọ, Gómìnà Ana tí ipinlẹ Eko ni ki àwọn ọmọ Orilẹ-ede Nàìjíríà bọ̀wọ̀ fún ìṣèlú.

Ó sọ pé “Òní ati lẹ́yìn Òní, mo fẹ́ sọ fun Awọn Ọmọ Orilẹ-ede Naijiria ki wọn bọ̀wọ̀ fún Òfin, nitori ibasepo mi pẹ̀lú àwọn ènìyàn jákèjádò ipinlẹ mẹ́rindínlógoji jẹ́ ki n mọ pé àṣeyọrí mi dájú”.

Olubunmi Adeyẹmọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button