Take a fresh look at your lifestyle.

Àyá Ààrẹ Orílẹ̀-èdè America Ṣé Àbẹwò Sí Nàmíbíà

0 400

Àyà Ààrẹ Orílẹ̀-èdè America, Ìyàáfín Dr Jill Biden ló ọjọ́ Kejì ní Namibia bí ó ṣé ṣàbẹwò sí Àjọ Hope Initiative Southern Africa.

Ó jẹ́ àjọ kan tí kì í ṣe ti ìjọba tí ń ṣiṣẹ́ láti fòpin sí òṣì àti ebi ní àwọn àgbègbè tí a yà sọ́tọ̀ ní gedegbe ní ẹkùn náà.

Díẹ̀ nínù àwọn ètò wọ́n ní ọ̀nà látí ṣé ádínkù ààrùn HIV tuntun àtí ẹtọ dọgbadọgba láàrín akọ atí abó èyí tí PEPFAR ṣé onigbọwọ rẹ̀.

Arábìnrin náà sọ pé, “O má ń jẹ́ òun ìwúrí fún òún látí rí Obìnrin gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Orílẹ̀-èdè èyíkéyìí, ìdí níyì tí mó ṣé má ń ṣé àtìlẹ́yìn fún gbogbo obìnrin tó bá jáde fún ipò kan tàbí òmíràn.”

Tún kà nípa:Namibia yan olùdíje ààrẹ bìnrin ní ìgbà àkọ́kọ́ fún ọdún 2024

Ìyàáfín náà àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ Naomi Biden yóò ṣé àbẹwò sí Kenya lẹyìn àkókò wọ́n ní Namibia.

Ó jẹ́ ibẹwo ẹlẹ̀ẹ́kẹ́fà tí Biden yóò ṣé lápapọ̀ sí ilẹ̀ Afríkà, ṣùgbọ́n ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀ rè gẹ́gẹ́ bí Ìyàáfín Ààrẹ Orílẹ̀-èdè America. Ó tún jẹ́ ibẹwo àkọkọ́ rẹ̀ sí Namibia.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button