Ní ọjọ́ Ẹtì ni Orílẹ̀ Èdè Lybia se ayẹyẹ ọdún kejìlá ní ìrántí olóògbé ààrẹ orílẹ̀ èdè náà tẹ́lẹ̀ rí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ó wà ní ìlú Tripoli àti àgbègbè rẹ̀ ni wọ́n tú yááyá fún ìrántí akọni náà pẹ̀lú Àsìá Orílẹ̀ Èdè náà lọ́wọ́ wọn.
Ìròyìn fi yéwa pé, orílẹ̀ èdè Lybia wà ní àsìkò wàhálà ìṣèjọba tí orílẹ̀ èdè náà sì pín sí méjì, pẹ̀lú bẹ́ẹ̀, gbogbo ojú pópó ni ó kún fún àwọn ènìyàn tí inú wọ́n sì ń dùn ní ìrántí Ààrẹ Moammar Gadafi.
Gadafi, Eni tí àwọn Orílẹ̀ Èdè àgbáyé gba agbára lọ́wọ́ọ rẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án jẹ́ ẹni àì-lègbàgbé lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀.
Leave a Reply