Àjọ elétò ìdìbò ni Democratic Republic of Congo ti sọ wí pé Ìforúkọsílẹ̀ fún àwọn Olùdìbò ti bẹ̀rẹ̀ ní ẹkùn méje ní ìlà oòrùn Orílẹ̀-èdè náà
Ìròyìn ró pé, ìlà oòrùn Orílẹ̀-èdè náà ní ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀kẹ́ àìmọye ọmọ orílẹ̀-èdè náà ti di ìsáǹsá àti alárìnkiri látàrí ìjà láàrín ọmọ ogun orílẹ̀-èdè náà àti àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀.
Ètò náà jẹ́ ìforúkọsílẹ̀ tó kẹ́yin kí ètò ìdìbò gbogbo gbò tó wáyé ní oṣù Kejìlá ọdún yìí.
Àjọ elétò ìdìbò sọ pé wọ́n o se ìforúkọsílẹ̀ fún àwọn Olùdìbò ní agbègbè tó le bíi Ituri àti Ariwa ilu Kivu, àti ní orile-ede US àti Canada..
Ìforúkọsílẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ní oṣù Kejìlá, àwọn ènìyàn Mílíọ̀nù méjìlá sì ti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọ elétò ìdìbò se sọ.
Ìwà ìpáǹle ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà ti fán àwọn ènìyàn bí Mílíọ̀nù mẹ́fà ká kiri tí wọn kò nílé lórí mọ́, tí wọ́n ṣì niíò oúnjẹ láti jẹ, gẹ́gẹ́ bí àjọ UN se sọ
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply