Take a fresh look at your lifestyle.

NPFL: Bendel Insurance Fákọ̀yọ́ Ní Ìbàdàn

0 305

Bendel Insurance tèsíwájú lórí bí wọ́n ṣé ń fakọyọ nínú ìdíje Nigeria Professional Football League (NPFL) ní ifẹsẹwọnsẹ keje tí sáà ìgbábọ́ọ̀lù 2022/2023 lẹyìn tí wọ́n gbà àmì ayò méjì 2-2 pẹ̀lú Shooting Stars, ní Lekan Salami Stadium ní Ibadan, Ìpínlẹ̀ Oyo.

Iyalẹnu ló jẹ́ bí Bendel Insurance ṣé gbá àmì akọ́kọ̀ wọ̀lé ní ìṣẹ́jú kíní látí ẹ̀sẹ̀ Imade Osarenkhoe. Ní ìṣẹ́jú kẹtadinlogoji, Ismail Seriki gbá àmì ayò Kejì wọlé fún ikọ́ Bendel Insurance 2-0.

Tún kà nípa:NPFL: Enyimba Lú Nasarawa United 2-1 Ní Ìlú Jos

Ẹ̀wẹ̀, Shooting Stars náà dá àmì ayò kàn padà bí Malomo Ayodeji ṣé mí àwọ̀n ṣáájú ìparí ìpele àkọ́kọ́. Ní ìpele Kejì ní Opeoluwa Olufemi gbá àmì ayò Kejì wọlé fún Shooting Stars ní ìṣẹ́jú kẹ́talélọ́gọ́ta látí jẹ́ kí Ifẹsẹwọnsẹ náà parí sí ọ̀mì.

Àwọn àbájáde Ifẹsẹwọnsẹ NPFL ní ọjọ́ Àìkú

Ẹ̀ka A

El-Kanemi Warriors 1-1 Akwa United

Remo Stars 1-1 Plateau United

Ibon Stars 2-2 Bendel Insurance

Ẹ̀ka B

Abia Warriors 1-1 Wikki Tourists FC

Rangers International 1-0 Doma United

Lobi Stars 2-1 Dakkada FC

Sunshine Stars 2-0 Niger Tornadoes

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button