Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ọmọ Ogun Ọlọ̀tẹ̀ Orílẹ̀-èdè Chad Yóò Kojú Ìdájọ́ Látàrí Ikú Ààrẹ

0 277

 

Orílẹ̀-èdè Chad yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ àwọn ọmọ ogun ọ̀lọ̀tẹ̀ bí àádọ̀jọ tí wọn gbàgbọ́ pé wọ́n sekú pa ààrẹ Idriss Déby.

Ìgbẹ́jọ́ yóò wáyé ní Kléssoum, ọgbà ẹ̀wọ̀n ti ààbò rẹ múná dóko, ìròyìn abẹ́lé láti ọ̀dọ̀ ẹ̀rọ ayélujára sọ bẹ́ẹ̀.

Àwọn afunrasí jẹ́ ti ẹgbẹ́ Front for Concord and Change in Chad (FACT), ọmọ ẹgbẹ́ olọ̀tẹ̀ tó se ìkọ̀lù ìdìtẹ̀gbàjọba
láti ẹ̀yìn wá, ní Orílẹ̀-èdè Libya ní 2021.

Idriss Deby ni wọ́n pa ní ọsù kẹrin ọdún
2021 nígbà tí ó ń ṣáájú Ìkọ Ológun láti lé àwọn ọmọ ogun olọ̀tẹ̀ sẹ́yìn.

Wọ́n fi ẹ̀sùn jàgídíjàgan, fífi ọmọdé sínú ológun, lílo ológun láti ìta, kíkó iyán ológun orilẹ̀-ède náà kéré àti dídá ẹ̀mí ààrẹ légbodò kàn wọ́n.

Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yege nínú ìfìbò yàn sípò rẹ̀ tí wọ́n sọ pé óò ni ọwọ́ kan àbòsí nínú.

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ orílẹ̀-èdè Faransé, adarí tuntun ológun ti Orílẹ̀-èdè Chad ní ore ọ̀fẹ́ láti lé àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ sẹ́yin.

Ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yin tí Deby ti kú, àjosoyépọ̀ pẹ̀lú ìkọ̀ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ àti ìjọba Chad ti forísọ́pán

Ẹgbẹ́ náà ti kọ ẹ̀yìn sí ọ̀rọ̀ ètò àlàáfíà, tí wọ́n ṣì pariwo fún Ìdásílẹ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button