Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Mallam Adamu Adamu, tí pàṣẹ kí wọ́n tí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga Káàkiri orílẹ̀-èdè yìí fún ìdìbò Ààrẹ àtí Gómìnà lọdún yìí.
Ìgbákejì Akọ̀wé Alàkóso Ọ̀gbẹ́ni Christopher Maiyaki tí National University Commission NUC, kéde ìlànà Mínísítà náà nínú lẹ́tà tó buwọ́lù, tó sí fí ṣọ́wọ́ sí àwọn ìgbákejì Adari àwọn Ilé-ẹ̀kọ́ gíga orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Maiyaki ṣé àkíyèsí pé ìlànà náà wáyé lẹyìn tí Mínísítà ṣé àwọn ifiyesi, ifọrọwerọ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò lórí ààbò òṣìṣẹ́, àkẹ́kọ́ àti àwọn òun-ìní tí àwọn Ilé-ìwé náà.
“Nitorinaa, àwọn Ìgbákejì Alàkóso àti àwọn Olùdarí/àwọn aláṣẹ tí àwọn ilé-iṣẹ́ láàrín àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ní látí tí àwọn Ilé-ẹ̀kọ́ gíga wọnyí pá bẹ̀rẹ̀ látí Ọjọ́bọ̀ ọjọ́ Kejì-lé-lógún 22 Oṣù Kejì ọdún 2023 sí Ọjọ́ Ìṣẹgun ọjọ́ kẹrinla 14 Oṣù Kẹta ọdún 2023,” Adamu sọ.
Lekan Orenuga
Leave a Reply