Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ń gbáradì fún ètò ìdìbò gbogbo gbòò ọdún 2023, Ọ̀gá Àgbà adarí ọmọ ogun òfurufú, Ọladayọ Amao gba àwọn ọmọ ogun níyànjú láti má se dásí òsèlú lójúnà àti siṣẹ́ wọn bí ó ti se yẹ.
Ó fi ọ̀rọ̀ náà léde nígbà tí ó sèpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn adarí ẹka kọ̀ọ̀kan ní ọ́ọ́fìsì àpapọ̀ àjọ náà ní ìlú Abuja.
Ọ̀gágun Amao gba àwọn adarí ikọ̀ kọ̀ọ̀kan níyànjú láti rán àwọn ọmọ ogun létí ojúse wọn àti ipa wọn nínú ètò òsèlú.
Ó sàfikún pé àwọn yóò se àgbéyẹ̀wò àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọ ogun tí yóò kópa nínú ètò ààbò lásìkò ìdìbò.
Leave a Reply