Àjọ Ọmọ Ogun ti ìpín alákọ̀kọ́ọ́ ní Ìlú Kaduna ti se àwọn agbésùmọ̀mí báṣu-bàṣu, tí ọgbọ̀n ènìyàn sì gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn esinsin-ò-kọkú náà. Ikọ̀ Ọmọ Ogun gba Alùpùpù méjì lọ́wọ́ọ wọn, Ó sì sọ òpópónà Kaduna sí Ìlú Abuja di lílò padà fún mùtú-mùwà.
Àwọn Ọmọ Ogun se alábàpádèé àwọn jàǹdùkù náà ní Ọjọ́bọ̀, nígbà tí wọ́n tẹ̀lé Ọ̀gágun Àgbà SE Udonwa, eni tí ó se àbẹ̀wò sí ikọ̀ Ọmọ ogun ní Ìlú Birnin Gwari.
Ọ̀gágun SE Udonwa gbóríyìn fún ikọ̀ Ọmọ Ogun fún ìwà akin àti ìfarajì wọn.
Leave a Reply