Ààrẹ Buhari pàrọwà sí gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti fún òun ní ọjọ́ méje kí ó fi yanjú ìsòro ọ̀wọ́n-gógó owó, èyí tí ó ti dá awuyewuye sílẹ̀ jákè-jádò orílẹ̀ èdè.
Ó fi ọ̀rọ̀ náà léde ní ọjọ́ Ẹtì, nígbà tí ó gbàlejò àwọn Gómìnà onítẹ̀síwájú, lójúnà àti wá ojútùú sí ìsòro owó náà. Ààrẹ tẹ̀síwájú pé òun ti rí ìsòro tí àwọn ará ìlú ń dojúkọ àti ìfàsẹ́yìn tí ọ̀wọ́n-gógó owó náà ti kó bá ọrọ̀ ajé, Ó wá se àdéhùn pé, láìpẹ́ jọjọ, ìsòro náà yóò di àfìsẹ́yìn tí egúngún ń fi aṣọ.
Ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Gómìnà fún àkíyèsí àti àtìlẹyìn wọn, Ó sì fi dáwọn lójú pé, òun yóò tán ìsòro náà.
[…] Tún kà nípa: Ààrẹ Buhari Gbé Ìgbésẹ̀ Akin Lórí Ọ̀wọ́n-gógó Owó […]