Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti rí àwọn ibùdó tí ara ilu sọ di akitan bíi mejilelaadọta ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orilẹ èdè Nàìjíríà tí o sì ti bẹrẹ sí ní palẹ wọn mọ.
Atẹjade kan ti Kọmisana fún Ìròyìn, Àṣà àti Ìrìn Àjò Afe, Omowe Wasiu Olatubosun fi síta ló fihàn pé ọkọ ako’doti ilé iṣẹ tó n sọ idọti di ohun èlò tuntun, Mottainai Recycling Ltd lo ti n lọ káàkiri láti palẹ àwọn idọti náà mọ kúrò níbi tí àwọn èèyàn sọ di akitan.
Atẹjade náà jẹ ki o di mímọ pé, awọn ibi ti wọ́n ti sọ dì akitan láàrin ìgboro ìlú ìbàdàn bíi Mokola, Jembewon, Eleyele, Urban Day, Òpópónà Ife atijọ, àti Iyaganku ni ìjọba tí palẹ wọn mọ, nígbà tí ìjọba sí tún yan ìgbìmò amuseya tí yóò máa ṣe amojuto kiko idọti, tí àwọn míràn tí ọrọ náà kàn yóò sì máa ṣe àwárí àwọn ibùdó míràn ti wón ti sọ di akitan.
Kọmisana wá gba àwọn ará ìlú níyànjú láti ta kété sí ìwà sísun idọti ṣugbọn ki wọn máa palẹ idọti wọn mọ́ sínú àpò ko ba le rọrun láti gbé fún àwọn ọkọ ako’doti ilé iṣẹ ti ìjọba gbà láti máa kó idọti dànù ki ìlú ìbàdàn bà lè ṣe gbé fún onílé àti àlejò.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply