Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra, gúsù iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Chukwuma Charles Soludo, CFR ṣe ìrántí ikú àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ fún orílẹ̀-èdè.Ó gbóríyìn fún ọmọ ogun Nàìjíríà fún iṣẹ́ takuntakun wọn lórí ààbò orílẹ̀-èdè.
Gómìnà Sólúdò ṣe ìgbóríyìn yìí lásìkò ayẹyẹ gbígbé fúláwà sí ibojì láti ṣe ìrántí àwọn ọmọ ológun fún ọdún 2023, ní gbọ̀ngàn Dokita Alex Ekwueme,ní ìlú Awka, olú-ìlú náà.
Gómìnà náà ṣàpèjúwe ọjọ́ náà bíi ọjọ́ àròjinlẹ̀.
Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú kíkí gbogbo ọmọ ìlú kú ayẹyẹ ọdún ìrántí àwọn ọmọ ogun, tí ó sì sọ pé kí wọ́n túnbọ̀ máa gbàdúrà fún àwọn akọni tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Leave a Reply