Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdíje CHAN 2023: Okocha Àti Àwọn Làmìlaka Míràn Ní Ilẹ̀ Adúláwọ̀ Yóò Wá Ní Ìkàlẹ̀ Níbi Ayẹyẹ Ìsíde

0 277

 

Ògbóǹtarìgì ẹlẹ́sẹ̀ ayò àti agégèàrà agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀rí ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nì Austine Jay Jay Okocha ni wọ́n ti fìwé pè sí ibi ìsíde ìdíje Championship of African Nations (CHAN) ti ọdún 2023.

 

Okocha kópa nígbà márùn ún nínú ti ìdíje African Cup of Nations, o tún wà lára àwọn ikọ̀ olóríre tó gba ife ẹ̀yẹ náà ní ọdún 1994 ní Orílẹ̀-èdè Tunisia.

 

Pẹ̀lú Okocha, agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Algeria tẹ́lẹ̀, Rabah Madjer, tún wà níbẹ̀. Ó sin Orílẹ̀-èdè rẹ̀ ní ìgbà mọ́kàndínlógún, ó kópa ní ìdíje àgbáyé ní ìgbà méjì, 1982 àti 1986 àti ìdíje ife ti ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní ọdún 1990.

 

Samuel Eto’o, olórí ti àjọ Cameroon Football Federation, àti Olúborí àwọn agbábọ́ọ̀lù ti ilẹ Adúláwọ̀ ní ìgbà méjì náà yóò gunlẹ síbi ìdíje ńlá náà

 

Didier Drogba, Asamoah Gyan àti Yaya Toure náà kò ní gbẹ́yìn.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button