Orílẹ̀ èdè North Korea ti ju àdó olóró méjì sí ojú òkun ní ọjọ́ àìkú (Sunday) lójúnà àti rí àrídájú àṣeyọrí lóríi pípèsè àdó olóró náà.
Ìròyìn fi yé wa pé, adarí orílẹ̀ èdè náà, Kim Jog Un ni ó se àmójútó àgbéyẹ̀wò àdó olóró náà ní ọjọ́bọ̀ (Thursday) ní ibùdó kan tí wọ́n ti pèsè fún irúfẹ́ àgbéyẹ̀wò bẹ́ẹ̀.
Lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò náà, àrídájú wà pé àwọn àdó olóró méjéèjì náà le è rìn ìrìn àjò ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìlómítà (500km) tíí se máìlì ọ̀ọ́dúnrún lé mọ́kànlá (311miles).
Leave a Reply