Ìjọba orílẹ̀ èdè Nigeria àti India ti fi ìmọ̀ sọ̀kan láti gbógun ti gbígbé àti lílò oògùn olóró, àti láti fún àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó ń gbógun ti lílo oògùn olóró náà, Nigeria Drug Law Enforcement Agency, NDLEA ní agbára fún ìkésẹjárí iṣẹ́ wọn.
Àfẹnukò náà wáyé lẹ́yìn ìpàdé ọlọ́jọ́ méjì, èyí tí ó wáyé ní New Delhi ní orílẹ̀ èdè India láàrin àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ń gbógun ti oògùn olóró ní orílẹ̀ èdè méjéèjì. Àdéhùn wáyé láti ri dájú pé wọ́n pinwọ́ gbígbé oògùn olóró, lẹ́yìn náà wọ́n sì pinnu láti ṣe ìpàdé míràn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọdún 2023.
Ọ̀gá àgbà àjọ náà, ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ajagun fẹ̀yìntì Brig. Gen. Mohammed Buba Marwa tí ó kó àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ sòdí lọ sí ìpàdé náà sọ pé, ìpàdé náà se pàtàkì léyìí tí yóò sì so èso rere àtipé ìbásepọ̀ náà yóò tẹ̀ síwájú.
Leave a Reply