Mínísítà fún ìmọ̀ ìjìlẹ̀, ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ohun àtinúdá ( Minister of Science Technology and Innovaton) Dokita Adeleke Mamora sọ wípé, ibùdó ìmọ̀ ìjìlẹ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ se pàtàkì fún ọrọ̀ ajé àti ìfagagbága pẹ̀lú orílẹ̀ èdè àgbáyé nípa ìpèsè ohun èlò.
Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ìlú Abuja níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan nípa lílo ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fún ìdàgbàsókè àwùjọ wa. Mínísítà, ẹni tí akọ̀wé àgbà ẹka ìjọba náà, Arábìnrin Monilọla Udoh sojú fún se àfikún pé irúfẹ́ ibùdó bẹ́ẹ̀ ti jẹ́ àseyọrí nla fún àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé tí óti se irúụ rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ àgbáyé tí ó ń mójú tó ibùdó sáyẹ́ǹsì náà se sọ, ibùdó ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ìjìlẹ̀ ní ìrankàn láti pèsè ọrọ̀ sí àwùjọ àti orílẹ̀ èdè, ìpèsè ohun àtinúdá àti ìfagagbága fún ìgbòòrò ọrọ̀ ajé.
Leave a Reply