Take a fresh look at your lifestyle.

Àṣeyọrí Aláìlẹ́gbẹ́ Morocco Yóò Ran Bọ́ọ̀lù Gbígbá Ilẹ̀ Adulawọ Lọ́wọ́

0 352

 

Akọ̀wé gbogbo-gbòò ti CAF Mosengo-Omba ti sọ pé àṣeyọrí ńlá ti ẹgbẹ́ agbábọ́ölù Morocco ní Ìdíje ife àgbáyé tó ńlọ lọ́wọ́ yóò fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù yókù ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní ìtara láti lè se dáadáa síi lọ́jọ́ iwájú.

 

Ẹlẹ́sẹ̀ ayò Morocco, Youssef En-Nesyri gbá bọ́ọ̀lù kan dondo ṣí àwọ̀n ní abala àkókò ní pápá ìseré Al Thumama, tí wọ́n ṣì borí ní ayò kan sódo.

 

Ó ṣeéṣe kí ilẹ̀ Adúláwọ̀ máa ní àwọn akópa ní ipele tó kángun sí àsekágbá àti àsekágbá Ìdíje bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá àgbáyé, Mosengo-Omba sọ bẹẹ.

 

Orílẹ̀-èdè Morocco yóò kojú orílẹ̀-èdè France alátakò wọn ní ipele tó kángun sí àsekágbá ní ọjọ́ Ojọ́rú ní pápá ìseré Al Bayt.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button