Take a fresh look at your lifestyle.

Abẹ́rẹ́ Èbólà Dé Sí Uganda Fún Ìdánrawò

0 464

 

Orílẹ̀-èdè Uganda ti ri ẹgbẹ̀fà abẹ́rẹ́ Èbólà gba fún ìdánrawò tí Sudan strain ti Èbólà.

 

Ìròyìn rò pé, méjilélógóje ti Sudan strain ti Èbólà ti wà, maírùnléládọ̀ta ènìyàn ti jẹ́ ọlọ́rùn ní ìpè nígbàtí wọ́n ti kéde àjàkálẹ̀ àrùn náà ní oṣù kẹsán án.

 

Kò tí sí àrídájú ògùn kankan tó leè dojúko àrùn náà kò sì kápá rẹ̀ pátápátá.
Abéré tó dé náà ni wọn yóò lò fún àwọn ènìyàn tó ti fara kásá tàbí súnmọ́ àwọn ènìyàn tó ti lùgbàdí àrùn náà.

 

Abéré náà ni wọ́n ṣe láti ọwọ́ àjọ Sabin ní Améríkà tí wọ́n ṣì yọ̀ǹnda rẹ̀ fún Orílè-èdè Uganda. Wọ́n dánwò, ó ṣì dára fún ìlò ọmọ ènìyàn.

 

Kòsí ọ̀tun àwọn ènìyàn míràn tó lùgbàdí àrùn náà ní orílẹ̀-èdè Uganda, àwọn tí wọ́n gbé lọ sí ilé ìwòsan látàrí rẹ̀ ni wọ́n ti dá padà sílé pẹ̀lú àlàáfíà ni ògbónjọ́ oṣù kọkànlá.

 

Àwọn ènìyàn sọ wípé, ìgbà tí àrùn náà lọ tán ni wön ṣẹ̀ṣẹ̀ kó àbẹ́rẹ́ wá, síɓẹ̀síbẹ̀ Mínísítà fún ètò ìlera, Dr. Jane Aceng sọ pé ó se pàtàkì láti ró àwọn ènìyàn lágbára láti dènà onírúurú àìsàn tàbí àrùn tó tún leè jẹyọ lọ́jọ́ iwájú

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button