Aya Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger, Dókítà Amina Abubakar Sanni Bello ti fi àìdùnnú rẹ̀ hàn fún ìfàsẹ́yìn àwọn obìnrin níbi ipò adarí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Dókítà Amina sọ ọ̀rọ̀ náà níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ipa àwọn obìnrin nínú ipò adarí, èyí tí ikọ̀ mùsùlùmí kan se agbátẹrù rẹ̀ ní ìlú Minna, olú ìlú ìpínlẹ̀ Niger. Ó tẹ̀ síwájú pé, ètò náà wáyé láti jẹ́ kí àwọn obìnrin mọ ojúse wọn àti oun tí Quran àti òjísẹ́ Ọlọ́run sọ nípa kí obìnrin jẹ́ adarí. Ó pèpè fún ìgbàláàyè àwọn obìnrin sí ìdàgbàsókè àwùjọ wa.
Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ pàtàkì fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, ọ̀jọ̀gbọ́n Usman Shuaib, Ọ̀mọ̀we Ibrahim Usman àti adájọ́ àgbà M.A. Hambali ni wọ́n fi rinlẹ̀ pé ó se pàtàkì fún obìnrin mùsùlùmí láti kópa, wà ní ipò adarí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Leave a Reply