Take a fresh look at your lifestyle.

Ènìyàn Mẹ́ta Gba Òmìnira Nígbà tí Ọwọ́ Tẹ Àwọn Agbésùmọ̀mí Ní ìpínlẹ̀ Zamfara

0 207

Àwọn ọmọ ogun  Nàìjíríà (Forest Sanity) ní ìpínlẹ̀ Zamfara ti yọ àwọn ènìyàn mẹ́ta tí ó wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé, tí wọ́n sì ti gba òmìnira. Wọ́n gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan ìjà olóró, alùpùpù ọgbọ̀n (30) lọ́wọ́ àwọn agbésùmọ̀mí ní ìpínlẹ̀ Zamfara.

 

Gẹ́gẹ́ bí ó ti se sọ, nígbà tí àwọn ọmọ ogun àti àwọn agbésùmọ̀mí da ojú ìjà kọ arawọn, ọwọ́ dun àwọn ajínigbé náà, wọ́n sì fi ibùba wọn sílẹ̀ pẹ̀lú fífi ẹsẹ̀ fẹ, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn sì fi ara gba ọta ìbọn.

 

Àjọ ọmọ ogun gbé òsùbà fún àwọn ọmọ ogun ( Forest Sanity) fún síse akin àti iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n se, wọ́n sì gba ará ìlú ní ìyànjú láti kún àwọn ọmọ ogun lọ́wọ́ lójúnà àti pèsè ààbò tí ó yarantí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button