Ènìyàn Méjìlélógún Wà Ní Àtìmọ́lé Látàrí Ìsẹ̀lẹ̀ Àdó Olóró Ní Orílẹ̀ Èdè Turkey
Àjọ ọlọ́pàá orílẹ̀ èdè Turkey ti àwọn afurasí méjìlélógún (22) mọ́lé látàrí àdo olóró tí ó bú gbàmù ní Istanbul. Ènìyàn mẹ́fà (6) pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí àwọn mọ́kànlélọ́gọ́rin (81) mínràn fi ara pa yánna-yànna ní ibùdó ìtajà kan.
Mínísítà tí ó wà fún ọ̀rọ̀ ìlú, Sulayman Soylu fi ẹ̀sùn kàn pé Kurdistan Workers Party (PKK) àti The Syrian Kurdish YGP jẹ́ afurasí níbi ìsẹ̀lẹ̀ láabi náà.
Ó tẹ̀ síwájú pé, arábìnrin afurasí kan tí ó wọ asọ tí wọ́n kọ NewYork sílára ni wọ́n ti fi àwòran rẹ̀ hàn ní ọ́ọ́fìsì àpapọ̀ àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀ èdè náà.
Àkọlù náà fi hàn dájú pé, onírúurú ìsẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tún le è wáyé síwájú ìdìbò ọdún 2023.
Leave a Reply