Manchester United yóò kojú ìkọ Barcelona ní ìdíje Europa League ní oṣù Kejì ọdún tó ń bọ̀.
Ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù Barcelona ṣubú sínú Europa League lẹyìn tó parí sí ipò kẹta ní UEFA Champions League, béèni Man Utd pàdánù ipò Kejì sí Real Sociedad.
Àwọn ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù méjèèjì tí kojú ará wọ́n ní ìgbà Mẹ́tàlá (13) ní ìdíje Yuroopu. Manchester United tí bóri mẹta pere nínú àwọn ìpàdé wọ̀nyí. Ìkọ Barcelona tí bóri Ifẹsẹwọnsẹ mẹrẹẹrin nínú àwọn ìpàdé wọ́n tó keyin, gẹ́gẹ́ bí aṣe kagba UEFA Champions League meji ni ọdún 2009 àti 2011.

Àwọn Ifẹsẹwọnsẹ àkọkọ́ yóò wáyé ní Oṣù Kejì ọjọ́ kẹrindilogun, Ọdún 2023, ṣáájú àwọn eré ipadabọ ní ọsẹ kàn lẹyìn náà.
Lekan Orenuga
Leave a Reply