Orílẹ̀ èdè Chad ti kéde kí onílé gbélé ní N’Djamena, Moundou, Doba-Koumra láti dènà ìwọ́de àti fífi èhónú hàn. Eléyìí kò sẹ̀yìn ìsẹ̀lẹ̀ láabi tí ó sẹlẹ̀ ní ọjọ́bọ̀, nígbà tí àwọn agbófìnró dáná ìbọn yá àwọn olùwọ́de tí wọ́n sì gba ẹ̀mí ènìyàn tí kò dí ní ọgọ́ta tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì fi ara pa yánna-yànna.
Àwọn olùwọ́de ń pè fún fífi ipò sílẹ̀ Mahamat Idris Deby Itno, ẹni tí ó gba ipò lẹ́yìn tí wọ́n se ikú pa bàbá rẹ̀ ní osù méjìdílógún sẹ́yìn.
Mínísítà fi léde pé, ètò ìséni mọ́lé náà yóò tẹ̀ síwájú títí tí àlàáfíà yóò fi joba ní orílẹ̀ èdè náà.
Leave a Reply