Àjọ tí ó ń mójú tó ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́, Mecca, ti fi léde pé gbogbo ètò ti parí láti dá owó padà fún àwọn tí kò ní ànfààní láti kópa níbi ètò Hajj ọdún 2022.
Asojú ikọ̀ náà Hajiya Fatima Usara ni ó fi àrídájú náà léde ní ìlú Àbújá nígbà tí ó ń dáhùn sí ìbéèrè ìjọ tí kìí se ti ìjọba kan lórí ọ̀rọ̀ owó náà.
Àjọ náà pa àrọwà sí gbogbo ẹka ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan láti se ojúṣe wọn kí ètò náà ba à lè yá kíákíá.
Leave a Reply