Ẹgbẹ́ Àwọn Ìyàwó ọlọ́pàá Ṣe Ìrànlọ́wọ́ Fún Àwọn Tí Ó Lùgbàdì Omíyalé Ní Ìpínlẹ̀ Kogi
Ẹgbẹ́ àwọn ìyàwo ọlọ́pàá ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí se ìrànlọ́wọ́ ohun ìrẹnilẹ́kún tí ó tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n náírà fún àwọn tí ó lùgbàdì omíyalé ní ìpínlẹ̀ Kogi
Ààrẹ ẹgbẹ́ náà tí ó jẹ́ aya ọ̀gá àgbà nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá, Hajia Alkali Baba ni ó kó àwọn ohun èlò náà fún àwọn tí ó fi ara káásá níbi ìsẹ̀lẹ̀ náà.
Hajia Baba rọ asojú àwọn tí ìsẹ̀lẹ̀ láabi náà sẹlẹ̀ sí láti jẹ́ kí ohun èlò náà kárí gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn.
Leave a Reply