Ààrẹ orílẹ̀ èdè Angola Joao Leurenco ti fi ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀ léde lẹ́yìn ìyànsípò rẹ̀ níwájú ilé ìgbìmọ̀ asòfin orílẹ̀ èdè náà, nígbà tí ó fi àrídájú ìfarajì rẹ̀ hàn fún ìdàgbàsókè ará ìlú.
Eléyìí wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí ó ti wà lórí oyè.
Angola jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ tí ó ń pèsè epo rọ̀bì ní ọ̀pọ̀ yanturu, sùgbọ́n pẹ̀lú bẹ́ẹ̀, ó ń bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè fínra. Ààrẹ tuntun náà se ìlérí àti mú òpin bá gbèsè náà.
Leave a Reply