Ààrẹ Muhammadu Buhari ti pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu fún àwọn tí ó lùgbàdì ẹ̀kún omi jákè-jádò orílè èdè Nàìjíríà.
Ọ̀gá àgb̀a tí ó ń mójú tó ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, Mustapha Ahmed ni ó fi ọ̀rọ̀ náà léde ní ìlú Abuja níbi àyájọ́ mímú àdíkù bá ewu ati òfò ti ọdún 2022 tí àjọ náà se agbátẹrù rẹ̀.
Ahmed sọ pé pínpín oúnjẹ náà sí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ti bẹ̀rẹ̀, ó sì fi àrídájú hàn pé, ohun ìdẹ̀kùn náà yóò kárí ilé- kárí oko títí òpin ọ̀sẹ̀.
Leave a Reply