Àìsàn Ebola ti tàn kálẹ̀ síi ní ìlú Uganda, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ti fi ara káásá àrùn náà, léyìí tí kò dín ní èèyàn métàlélógún sì ti gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra. Àjọ elétò ìlera ni ó fi ọ̀rọ̀ náà léde bẹ́ẹ̀.
Títàn kálẹ̀ àrùn náà súyọ ní ọjọ́ ìsẹ́gun, ní ìlú Mubende nígbà tí kòkòrò náà ti jẹ jáde ní àwọn ìlú bíi kyegegwa àti Kassanda. Èyí ló mú kí àpapọ̀ àwọn tí ó lùgbàdì àrùn náà pẹ̀lú àwọn tí ó ti kú jẹ́ mẹ́rìndínlógójì. Sùgbọ́n àìsàn Ebola náà kò ì tíì mú ọwọ́ dé ìlú Kampala.
Ìjoba pa àrọwà láti jẹ́ kí olúkúlùkù wà ní ojú ni alákàn fi ń sọ́rí, àti pé ó ti ń wá gbogbo ọ̀nà láti pinwọ́ àrùn náà.
Leave a Reply