Ààrẹ Muhammadu Buhari ti na ọwọ́ ìkíni kú oríire sí olórí ìjọba orílẹ̀ èdè Saudi Arabia tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ yàn Ọmọọba Muhammed Bin Salman ( MBS). Nínú àtèjísẹ́ kan tí ó fi ọwọ́ sí, Ààrẹ sọ wípé ìyànsípò náà wà ní ìbámu, àtipé ó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè náà, nígbà tí olùdarí náà tún jẹ́ mínísítà fún ètò ààbò.
Ààrẹ tún sọ wípé,ìjọba àti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti gbáradì fún àjọsepọ̀ tí ó múná dóko pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Saudi arabia.
Ó sì gbà á làdúrà pé kí ọlọ́run fún-un ní ọgbọ́n, òye àti àlàáfíà láti fi tu ọkọ̀ orílẹ̀ èdè náà.
Leave a Reply