Àjọ to ń rísí eré bóọ̀lù ní orílè èdè Nàìjíríà (NFF) ti kọ̀wé sí i Àjọ eré bọ́ọ̀lù lágbayé (FIFA) pé kí wọ́n sún ọjọ́ ìdìbò tí yóò wáyé ní ogbonjọ́ oṣù yìí síwájú.
Nínú lẹ́tà kan tí akọ̀wé àpapọ̀, Muhammed Sanusi fọwọ́ sí sọ wípé àjọ eré bóòlù lágbayé n fẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ pé ó ń dásí eré bọ́ọ̀lù ilẹ̀ yìí ju bí ọ ṣe yẹ lọ.
NFF náà sọ nítiirẹ̀ pé, ẹ̀ka ètò ìdájọ́ orilẹ èdè yìí náà ń tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ kọjá ibi tí wọn fiwọ́n sí nínú eré bóòlù aláfẹsẹ gbá orílẹ̀-èdè yìí.
Ìròyìn kan láti orísun tó dára sọ pé, ìjọba
Amaju Pinnick fé dúró lórí àlééfà fún osù díẹ sí kí wọ́n sì ri wípé wọ́n gba ìyọ̀nda láti yí ọjọ́ ìbò padà.
Ó tún jẹyọ síwájú sí pé, èsì àjọ FIFA sí lẹ́tà ọ̀hún ni wọ́n fi sọ̀wọ́ sí Akọ̀wé àgbà pátápátá ṣí ètò eré ìdárayá.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply