Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Arsenal ti fi ìṣẹ̀kusẹ̀ ṣe Crystal palace lọ́wọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdíje eré bọ́ọ̀lù Premier league
Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Arsenal so bẹ́ẹ̀, osi ribe o, won ni àrà tuntun làwọn gbé wá sí ìdíje Premier League lọ́tẹ̀ yí.

Arsenal na Crystal Palace ní àmì ayò méjì sodo. Wọ́n mi àwọ̀n Crystal palace lẹmeji, wọ́n da ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Crystal palace ríborìbo lórí pápá, Crystal palace gbiyanju gan ni ṣùgbọ́n àye góòlù o yo sílẹ̀ fún wọn

G. Martinelli ló kọ́kọ́ mi awọn ni ogún ìsẹ́jú nígbà tí ọmọ ẹgbẹ́ agbaboolu Crystal palace, M. Guehi náà mi àwọ̀n sínú ilé rẹ̀ tí àwọn eleyinbo npe ni OWN GOAL ni iṣẹju márùnlélọ́gọ́rin, eyi to je ànfàní nla fún arsenal.
Ọláyinká Akíntọ́lá.
Leave a Reply