Àlhájì Kurun Maiyama ti ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, ní ìjọba ìbílẹ̀ Maiyama ní ìpínlẹ̀ Kebbi, ti kúrò pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé díè àti àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ lọ sí ẹgbẹ́ All Progressive Congress, APC.
Àwọn ènìyàn tó kúrò ni wọ́n gbà tọwọ́ tẹsẹ̀ ní àpèjọ kan ní ìlú Maiyama ní ọjọ́ Ísẹ́gun. Ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn àti onílé àti àlejò ló péjọ síbi àjọ ńlá náà.
Nígbà tó ń kéde ìkúrò rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó sá kúrò pẹ̀lú rẹ̀ láti PDP, Maiyama sọ pé àwọn ọgbọ́n ìsàkóso, àseyorí àti ọgbọ́n àtinúdá lákókò ajakálẹ̀-àrùn Covid-19 ti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kebbi, Ọ̀gbẹ́ni Abubakar Àtíkù Bagudu, ni o mú wọn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply