Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ àpapọ̀ buwọ́lu iye owó tótó Bílíọ́nù méjì ààbọ̀ dọ́là Fún èbúté Bàdágìrì Ní Ìlú Èkó

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 238

Ìgbìmọ̀ Aláse àpapọ̀ ti fọwọ́sí iye owó tí ó tó bílíọ́nù méjì ààbọ̀ dọ́là fún àtúnṣe èbúté Bàdágìrì ní Ìpínlẹ̀ Èko, gúsùùl iwọ̀ oòrùn,orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Minisita ti eto gbigbelọ ati bibọ, Muazu Sambo, ẹniti o ṣafihan eyi ni ipari ipade minisita  ọsẹ yii, sọ fun Awọn oniroyin pe wọn yoo ṣe iṣẹ akanṣe naa  labẹ eto ajọṣepọ aladani-tijọba.

Gẹgẹ bi o ti sọ, ile-iṣẹ aladani yoo na owo sinu ibudo naa, ati ṣakoso rẹ fun ọdun marunle-logoji.

Sambo sọ pe igbesẹ ti ijọba  gbe yii yoo tunbọ mu ipinnu rẹ duro lati sọ Naijiria di ibudo okun  awọn agbegbe Iwọ-oorun ati Ariwa Afirika.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button