Ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀ fọwọ́sí owó tí ó ju Bílíọ́nù méjì ààbọ̀ Náírà lọ Fún ríra àwọn ọkọ̀ ìwúlò ayọ́kẹ́lẹ́ àti Àwọn ohun èlò fún àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò tí ń ṣiṣẹ́ ní olú-ìlú (FCT),Àbújá.![]()
Minisita olu-ilu FCT, Mohammed Bello fi eyi han lakoko ti o n ṣe alaye fun Awọn oniroyin Ile-igbimọ lori awọn ipinnu ti wọn ṣe nibi ipade awọn minisita ti Ọjọru ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe adari ẹ.
Lafikun, o sọ pe o tun fọwọsi rira awọn irinṣẹ diẹ sii fun awọn ile-iṣẹ aabo olu-ilu, FCT.

O sọ pe atilẹyin ti wọn fun awọn ile-iṣẹ aabo wa ni ibamu pẹlu eto imulo iranlọwọ iṣakoso olu-ilu lori iṣẹ wọn, ki aabo to peye le wa laarin agbegbe naa.
Leave a Reply