Take a fresh look at your lifestyle.

Kò sóun tó jọ bẹ́yẹn mọ́,ó tó gẹ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 317

Ọ̀ga àgbà fún Àwọn ọlọ̀pàá ní Nàìjíríà, IGP Usman Alkalli ti pàṣẹ fífagilé  gbogbo lílo nọ́ḿbà ìdánimọ̀ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ fún àwọn tí kìí ṣe ọlọ́pàá SPY Vehicle Number Pylates,tí àwọn tó ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ń lò  káàkiri àwọn ìpínlẹ̀  lápapọ̀ láìyọ ẹnìkankan sílẹ̀.

Fifagile naa wa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun awọn ọlọpaa , CSP Olumuyiwa Adejobi fọwọ si, o sọ pe boya eyi ti wọn fun laṣẹ lati lo ni tabi  rara,o ti di fifagile ni bayii.

Alaye naa tun sọ pe aṣẹ naa jẹ pataki lati yago fun aibikita  fun awọn ofin ati ilana irinna ni gbogbo igba ati awọn ofin miiran ti n ṣe itọsọna lilo opopona  awọn ẹni-kọọkan ti  farapamọ labẹ anfani nọmba ọlọpa SPY.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button