Àjọ tó ń mójútó ètò ọkọ̀ òfurufú lórílẹ̀-èdè Saudi Arabia, GACA, ti fọwọ́sí sísún àsiko láti gbé àwọn tí ń ṣe Hajj ní Nàìjíríà wọlé síwájú lábẹ́ ìṣàkóso ìgbìmọ̀ tó ń rísí ètò Hajj lórílè-èdè Nàìjíríà, NAHCON.
Igbimọ naa sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan ti Hajiya Fatima Sanda Usara, Oluranlọwọ Alakoso,lori ọrọ gbogbogboo, NAHCON fọwọ si.
Gẹgẹ bi alaye naa. “Afikun naa yoo bẹrẹ lati oni ọjọ kẹrin titi ọjọ kẹfa, fun ọkan ninu awọn ọkọ ofurufu naa, ti wọn si tun ti fọwọsi ọjọ kẹrin ati ikarun fun omiran. NAHCON beere fun isunsiwaju yii lati jẹ ki wọn le gbe awọn arinrin ajo ti o ku lọ si Ilu naa fun Hajj ọdun 2022.
Leave a Reply