Àjọ tó ń mójútó ètò Hajj lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NAHCON sọ pé òun ń ṣa gbogbo ipá òun láti ri dájú pé Nàìjíríà gba ààyè Hajj ẹgbẹ̀rún márùn ún si, ní àfikún fún àwọn arìnrìn àjò mímọ́ Hajj 2022 láti Sáúdí Arábíà.
Kọmisọna NAHCON fun irin ajo naa, Alhaji Abdullahi Hardawa, ti o sọ ọrọ naa ni Madina, Saudi Arabia sọ pe Alaga Igbimọ, Alhaji Zikirullah Hassan ti kọkọ ṣe ipade pẹlu Awọn Aṣoju ni Saudi Arabia ti o si beere fun afikun aaye.
Alhaji Hardawa sọ pe pataki abẹwo oun ni lati jẹ ki igbese naa ya kiakia ati lati rii daju pe o ṣe awọn oṣiṣẹ irin-ajo lanfaani ati awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lapapọ ti wọn fẹ ṣe ojuse ẹsin wọn ni ọdun yii.
Leave a Reply