Ilé-ẹjọ́ Guatemalan dájọ́ ẹ̀wọ̀n fún àwọn mẹ́jọ kan fún ṣíṣekúpa àwọn ọmọ ogun
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé-ẹjọ́ Ìlú Guatemalan ti ṣe ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọlójọ́ gbọọrọ fún ènìyàn mẹ́jọ kan fún ìṣekúpa àwọn ọmọ ogun mẹ́ta ní agbègbè abínibí kan nígbà tí àwọn ọmọ-ogun débẹ̀ láti ṣe ìwádìí gbígbé òògùn olóró káàkiri ní ọduń 2019.
Ẹgbẹ ọmọ ogun mẹsan kan wọ abule ariwa ila-oorun ti Semuy keji ni ọjọ 3, oṣu kẹsan ni ọdun 2019, ni wiwa ọkọ ofurufu kekere kan ati awọn papa ọkọ ofurufu ikọkọ ti wọn fura si pe wọn n lo fun gbigbe oogun.
Awọn olugbe ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ loju wọn fi ẹsun kan awọn ọmọ-ogun naa pe wọn wọ abule ti o wọnu naa, laaarin ọgba-ọpẹ ile Adulawọ kan ti wọn gbin, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn.
Awọn alaṣẹ fi ẹsun kan Cesar Montes, akikanju atijọ kan, ti o paṣẹ funwọn lati yinbọn fun awọn ọmọ ogun naa.
Leave a Reply