Take a fresh look at your lifestyle.

“A ko ni nnkankan ti a n fi pamọ o“ -Alakoso NNPC

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 239

Àjọ tó ń rí sí epo rọ̀bì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NNPC) ti fi ìgboyà kéde pé òun kò ní ǹkankan láti fi pamọ́ o,nígbàtí ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìròyìn ránṣẹ́ pè é.

Oludari Alakoso NNPC, Mallam Mele Kolo Kyari,ni o fi idi eyi mulẹ ni ọjọ iṣẹgun ni ilu Abuja.

Eyi jẹ bi Igbimọ Iṣiro Awujọ  Ile ti ṣe sọ pe ile-iṣẹ naa gbọdọ ṣafihan rẹ, awọn olori awọn ẹka mẹtadin-logun rẹ ti wọn fi ẹsun kan lori ijabọ ajeri iwe iṣiro owo  fun ijọba apapọ lori awọn aiṣedeede owo  laarin ọdun 2014 ati 2019.

Nigba to n soro nibi apejọ iwadii ti won tun bẹrẹ lori ijabọ ajẹri iwe iṣiro owo gbogbogbo, Alaga igbimo to n ri si iroyin gbogboogbo ile igbimo asofin, Oluwole Oke so pe igbese ajọ NNPC lati daabo bo awon ẹlẹgbẹ rẹ  je ifi nnkan  pamọ fun awọn ọmọ Naijiria.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button