Take a fresh look at your lifestyle.

‘Èmi yóò ri pé ìjọba ìbílẹ̀ ní òmìnira’,Hon.Abdulaziz

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 220

Ọmọ ẹgbẹ́ kan tó ń sojú agbègbè Keffi East, ní Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Násáráwá, Hon Abdulaziz Danladi, ti fi dá àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Keffi lójú pé òun múratán láti gbárùkù mọ́ ẹ̀tọ́ ìjọba ìbílẹ̀. Ó sọ pé òhun yóò ri dájú pé ìdàgbàsókè wọ ìgbèríko.

Hon. Abdulaziz,ti o jẹ Alaga Igbimọ Ile lori Awọn iṣẹ ati Ile,mu eleyi daniloju lakoko ti o n gbalejo igbimọ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ  (NULGE),ẹka ti ijọba ibilẹ Keffi  loni, ni ọfiisi rẹ ni Lafia.

Aṣofin naa sọ pe oun yoo ṣe atilẹyin lati ri pe ijọba ibilẹ ni ominira funra rẹ fun idagbasoke awọn igberiko ati fun  iranlọwọ ilọsiwaju awọn oṣiṣẹ  ijọba ibilẹ.

Aṣofin naa mu dawọn loju pe ohun yoo ṣoju wọn boṣe tọ ati boṣe yẹ ti  ni ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.

Alaga NULGE wa gboriyin fun Abdulaziz fun iṣẹ takuntakun to n ṣe.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button