Alukoro àgbà fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, IGP Usman Alkali Baba ti pàsẹ ìwádìí tó mọ́gbọ́nwá tí ó sì hàn gbangba lórí ẹ̀sùn gbígba owó bitcoin tí ó tó milionu mejilelogun naira lọ́wọ́ àwọn ará ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Eko; èyí tí wọ́n fi kan igbákejì alábòjútó ọlọpaa, Nwawe Cordelia àti àwọn míiràn ní ẹ̀ka ìwádìí òdarán (FCID) ní Alagbon, ilu Eko.
Eyi jẹyọ ninu atẹjade kan ti Komisona Ibatan Awujọ ti Agbofinro ti ọlọpa, CP Frank Mba fowọ si. O sọ pe agbekalẹ igbimọ iwadii pataki naa di pataki nitori iroyin to n lo kaari afẹfẹ lori ilowosi awọn ọlọpa lori esun ilọlọwọgba owo bitcoin to to milionu mejilelogun naira lọwọ awọn ọdọ Naijiria meji.
Leave a Reply