Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Zambia  Ṣetán Láti Mú ẹ̀kọ́ Ai Wọ Inú Ètò Ẹ̀kọ́ Wọn.

138

Ìjọba Zambia ti kéde ètò láti so ìmọ̀ ọgbọ́n àtọwọ́dá (AI) pọ̀ mọ́ ẹ̀ka ẹ̀kọ́ wọn láti ṣe àtìlẹ́yìn fún ẹ̀kọ́ tí ó dá lórí ìmọ̀ ní orílẹ̀-èdè náà.

Akọ̀wé fún àgbà fún ilé iṣẹ Ẹ̀kọ́, Kelvin Mambwe,  ló sọ èyí di mímọ̀  ninu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ìròyìn ìjọba ní ọjọ́ Àìkú, ó sọ wí pé ètò náà ni a ṣe láti mú kí iṣẹ́ kíláàsì sunwọ̀n síi, dín iṣẹ́ àwọn olùkọ́ kù, àti láti mú kí àwọn àbájáde ẹ̀kọ́ sunwọ̀n síi.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, gbígbà ìmọ̀ ọpọlọ yóò ran àwọn olùkọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ dáadáa, nígbàtí ó sì ń jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè dara pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ wọn.

Ó sọ wí pé ètò náà tún ní àwọn ètò láti sọ àwọn ilé ìwé dijita àti láti fẹ̀ sí i wíwọlé ìkànnì ayélujára káàkiri orílẹ̀-èdè náà, pàápàá jùlọ ní àwọn agbègbè ìgbèríko, láti pèsè àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fún ọjọ́ iwájú tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ń darí.

Akọ̀wé tun sọ wí pé àwọn irinṣẹ́ ìmọ̀ ọpọlọ yóò ṣe atìlẹ́yìn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àti àwọn ìgbòkègbodò lábẹ́ ẹ̀kọ́ tí ó dá lórí ìmọ̀ ọgbọ́n, nígbàtí ó ń so ètò ẹ̀kọ́ Zambia pọ̀ mọ́ àwọn ìlànà àgbáyé.

Comments are closed.

button