Take a fresh look at your lifestyle.

Ọdun Ileya: Aabo wa lEkoo- Ọbasa

O ṣe ileri ati ṣe ọpọ ofin ti yoo tu ara ilu lara

0 364

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa sọ pe alaafia n jọba ni Ipinlẹ Eko bayii. O ni eleyii ko ṣẹyin ijọba oloriṣi kan to fẹsẹ mulẹ lati ọdun 1999 ni ipinlẹ naa.

Ạṣofin Ọbasa sọrọ yii di mimọ ninu ọrọ ikini ku ọdun Ileya 2022 rẹ fun awọn ara ilu.

Oludari Ile naa woye pe ọdun Ileya n saami ifẹ, fifi ara jin funra ẹni ati fifi alaafia mulẹ laarin awujọ paapaa gẹgẹ bi ojuṣe musulumi ni asiko ọdun ati lẹyin ọdun.

Ninu ọrọ rẹ lo ti fi mulẹ pe, alaafia wa ni Ipinlẹ Eko fun irọrun awọn ara ilu ati awọn olokoowo, latari ifẹ ti awọn to wa ni ijọba ni fun igbe aye irọrun awọn ara ilu. O ni:

“Awọn ti ẹ yan lati ṣoju fun yin, ko kẹrẹ lati ri i daju pe wọn mu igbesi aye rọrun fun awọn ara ilu. A ti ṣe ofin ati awọn ipinnu ti yoo yanju eyi”

“Lara rẹ ni ofin to nii ṣe pẹlu ikọ alaabo ilu, iyẹn ‘Neighborhood Safety Corps’, ofin to jẹ mọ Gbigbogun ti iwa ifipamuni ati ẹgbẹ okunkun, eleyii ti yoo fiya to nipọn jẹ awọn to ba lọwọ ninu rẹ. Eyi lara awọn ofin ti yoo mu irọrun ba awọn ara ilu ti a n ṣe ninu Ile Igbimọ Aṣofin yii.

“Inu wa si dun si ohun ti a n gbọ lori awọn aṣeyọri yii laarin awọn ara ilu ati lati ọdọ awọn akẹgbẹ wa lati ita.” Nigba ti o n dupẹ lọwọ awọn olugbe ipinlẹ yii fun ẹmi ifarada sira wọn paapaa ni ti ẹsin, o rọ wọn lati ma ṣe dawọ ifẹ sira wọn duro.

Aṣofin Ọbasa fi eyi mulẹ ninu ọrọ ikini ku ọdun Ileya 2022, eyi ti Alukoro rẹ, Eromosele Ebhomele gbe jade.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button