Mínísítà fún Ìròyìn àti Àlàyé Orile-ede Naijiria, Mohammed Idris, tí tún sọ ìgbésẹ̀ Ààrẹ Bola Tinubu láti fí ìpìlẹ̀ tó lágbára sílẹ̀ fún ìdàgbàsókè ìgbà pípẹ́ ati pípín arisiki ká.
Mínísítà sọrọ náà nígbàtí o gbá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìdàgbàsókè ìjọba tiwantiwa fún Ààrẹ Tinubu 2027 (Grassroots Advocacy for Tinubu GAT 2027) ní àbẹwò ni Abuja, Nàìjíríà.
Gẹ́gẹ́ bí Idris ti sọ, ìjọba Tinubu tí gbé àwọn ìpinnu ìgboyà ati àwọn tó nira nígbà mìíràn kalẹ̀ láti gbé Nàìjíríà si ojuna tó yẹ, Ó tẹnu mọ pé àwọn àmì tí bẹ̀rẹ̀ sí i farahàn gbangba nínú ètò ọrọ-aje Orílẹ̀-èdè náà
Oluṣakoso gbogbogbò ẹgbẹ́ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ochugudu Achoda Ipuele, sọ pé ìdí ìbẹ̀wò náà ní láti fún Mínísítà náà níro lórí àwọn iṣẹ́ ẹgbẹ́ náà àti láti kún Mínísítà náà lọ́wọ́ lórí àwọn ifilede fún àwọn aráàlú Nàìjíríà àti láti ṣàlàyé àwọn ètò ìmúlò ìjọba.
O fi kún pé ẹgbẹ́ náà tí pinnu láti ṣé àtìlẹ́yìn fún àwọn ètò ìmúlò Ààrẹ Tinubu nípa títa kò àwọn tó ń dá ọrọ ru, pàápàá jùlọ l’akoko ìdìbò, àti nípa mímú àwọn ọdọ ṣiṣẹ́.
Comments are closed.