Àjọ Nigeria Basketball Federation (NBBF),ti sọ ní ọjó Ẹtì pé, Ikò Agbaboolu Sinu- àpẹrẹ àwọn Obinrin yóò kojú Ìkọ WNBA Indiana nibi ayò Ọlọ́rẹ̀sọ́rẹ̀ẹ́ láti gbaradi.

Oníròyìn àjọ NBBF, Akeem Buhari, lọ sọ èyí ní ọjọ Ẹti nígbà tí o sọ fún àwọn oníròyìn ní ìlú Eko.
Bí ọgbẹni Buhari ṣe sọ, ayò Ọlọ́rẹ̀sọ́rẹ̀ẹ́ náà yóò wáyé ní ọjọ Kejì oṣù Kàrún ùn ni Gainbridge Fieldhouse ni Indianapolis, United States.
Ó sọ pé ayò náà wà fún igbaradi fún ìkọ ti Indiana fún ìdíje WNBA championships to ń bọ̀ ní ọdún 2026.
Lara àwọn ògbóntàrigi Agbaboolu Sinu- àpẹrẹ ti wọn ń reti fún ìkọ mejeeji ní a ti rí Cathlin Clark of Fever ti Indiana àti Ezinne Kalu Phelps ti orílẹ-èdè Nàìjíríà.
Ni ìbẹ̀rẹ̀ ọsẹ yìí, àjọ NBBF kéde idije Ọlọ́rẹ̀sọ́rẹ̀ẹ́ laarin ìkọ D`Tigress ati ti Los Angeles Sparks ti yóò wáyé ní ọjọ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kẹrin.
Temitọ́pè Òbísẹ̀san