Ìgbákejì Ààrẹ tí Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Benjamin Okezie Kalu, tí yàn Gómìnà Ìpínlẹ̀ Enugu tẹ́lẹ̀ rí, Dókítà Okwesilieze Nwodo gẹ́gẹ́ bí olórí Ìgbìmọ̀ Ìsìnkú fún olóògbé Chukwuemeka Ezeife, Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí tí Ìpínlẹ̀ Anambra.
Nígbà tó n ṣé ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ náà nílùú Abuja, Kalu rọ́ ìgbìmọ̀ náà látí sá gbogbo ipá wọ́n kí ètò ìsìnkú náà lè jẹ́ èyí tó bú ìyí kún Olóògbé Ezeife, o sí fí dá lójú pé àwọn ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ wà lẹ́yìn rẹ̀.

Nwodo náà wá ṣé ìdánilójú pé àwọn yóò ṣé ètò ìsìnkú náà kó larinrin.