Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti pèsè Ọgọ́rùn-ùn ọkọ̀ ìpàráàro fún àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò, nígbà tó ṣèlérí láti kún wọn lọ́wọ́ lórí akitiyan wọn láti rí dájú wí pé ètò ààbò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Gómìnà lo sọ èyí di mímọ̀ lásìkò tó n jọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ náà fún ẹ̀ka tó n pèsè ààbò ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Nígbà tó n fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí iṣẹ́ takuntakun ti àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò náà ṣe ni ọdún 2023 pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà tó wáyé, Makinde lu àwọn adarí ẹ̀ka náà lọ́gọ ẹnu fún ìgbìyànjú wọn nípa ṣíṣe kóríyá fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka náà, o wá ṣèlérí pé ìṣèjọba òun ti ṣetán láti gbárùkù ti wọn.
Bákan náà ni Gómìnà fi àsìkò náà rọ àwọn adarí ẹ̀ka náà láti rí dájú wí pé wọn san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn lásìkò ki wọn ba lè ṣe iṣẹ wọn bóti tọ àti bóti yẹ.
Nínú ọrọ ikini káàbọ̀ rẹ̀, ẹni tíì ṣe olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ètò ààbò fún Gómìnà, Fatai Owoseni fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà fún akitiyan rẹ̀ láti rí dájú pé ètò ààbò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nípa ìpèsè ọkọ̀ àti àwọn ohun míràn.

Owoseni tẹnu mọ pé, eléyìí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ ti Gómìnà Seyi Makinde yóò pèsè irú ọkọ̀ bayii fún ẹ̀ka elétò ààbò ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà tó mẹnu ba bí Gómìnà ṣe ṣe irú èyí ni odun 2019 láti ṣe ayẹyẹ ọgọrun ọjọ́ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ní sáà kínní.
Nígbà to n fèèsì lórúkọ àwọn adarí òṣìṣẹ́ elétò ààbò náà ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gá ọlọ́pàá, Adebola Hamzat dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà fún àtìlẹ́yìn rẹ eléyìí tó mú kí ààbò àti àlàáfíà jọba ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ọ̀gá ọlọ́pàá tẹnu mọ pé igba keji leyi ti Gómìnà yóò pèsè ọkọ fún ẹka ètò ààbò ni ìwọ̀n oṣù mẹ́fà ti òun ti dé sí Ipinlẹ Ọ̀yọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá ọlọ́pàá
Abiola Olowe
Ibàdàn