Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Kéde Sisan Owó Òṣìṣẹ́ To Kéré jù Fún Oṣù Mẹ́fà Míràn

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kéde sisan Ẹgbẹ̀rún Márùndínlọ́gbọn (N25,000) fún òṣìṣẹ́ ìjọba àti Ẹgbẹ̀rún Márùndínlógún Náírà (N15,000)fún òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì fun oṣù mẹ́fà síwájú síi. Makinde ló kéde èyí lásìkò tó lọ ṣí òpópónà òní…

Ilé Aṣòfin Èkó rọ Ìjọba láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin tí wọ́n yin ohun èèlò tajú-tajú sí…

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó lábé Olùdarí Ilé Aṣòfin náà, Aṣòfin Mudashiru Ọbasá ti rọ Ìjọba láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún Ọmọdébìnrin Amina Alege, ọmọ ọdún méjìlá, akẹ́kọ̀ọ́ Ilé-ẹ̀kọ́ Girama Adam Yakubu Memorial High school ní Ìpínlẹ̀ Èkó fún…

Tí Ìjọba Bá kọ̀ Láti Mú Àdéhùn Tí Wọn Bá Ẹgbẹ́ Òsìsẹ́ Ṣe, NLC Yóò Gúnlè Ìwọ́de Ọlọ́jọ́ Méjì Ní Ọjọ́…

A ó gùnlé ètò ìwọ́de Ọlọ́jọ́ méjì ní oṣu ti a wa yii tí ìjọba kò bá mú àdéhùn tí wọ́n ṣe pẹ̀lú wa ṣẹ. Ààrẹ ẹgbẹ́ NLC Joe Ajaero ti ní ẹgbẹ́ oṣiṣẹ yóò gunle ètò ìwọ́de Ọlọ́jọ́ méjì ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ́n àti Ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ́n Oṣù Kejì…

Jibiti Orí Ẹ̀rọ Ayélujára: Ilé Ẹjọ́ Sọ Àwọn Mẹ́ẹ̀dógún Sẹ́wọn ní Ìlú Ìbàdàn

Onídàájọ́ Olusola Adetujoye, O.A. Lajide àti S.O. Adeyemi ti ilé ẹjọ́ gíga to jókòó ní ìlú Ìbàdàn ti sọ àwọn Mẹ́ẹ̀dógún sẹ́wọn látàrí bi wọn ṣe lọwọ nínú jibiti orí ẹ̀rọ ayélujára. Àwọn Mẹ́ẹ̀dógún náà ni wọn jẹbi ẹ̀sùn ti Àjọ EFCC fi kàn…

Ilé Aṣòfin Èkó mú ìmọ̀ràn wá tí owó náìrà yóò fi níye lórí sí owó dọ́là.

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó ké gbàǹjarì lórí bí owó náìrà ṣe ń lọ sílẹ̀ ní pàṣípààrọ̀ sí owó dọ́là. Nínú ìjíròrò Ilé Aṣòfin náà lọ́jo Ìṣẹ́gun (Tuesday) lábẹ́ Olùdarí Ilé Aṣòfin náà, Aṣòfin Mudashiru Ọbasá, ni wọ́n ti wòye pé, ní báyìí…

Ìpèníjà ààbò ìlú: Ilé Aṣòfin Èkó rọ Ilé Aṣòfin Àpapọ̀ láti ṣàtúnṣe sí ìwé òfin

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó rọ Ilé Aṣòfin Àpapọ̀ láti ṣàtúnṣe sí ìwé òfin láti lè wá ojútùú sí Ìpèníjà ààbò bí ìjínigbé, ìdigunjalè, àti àwọn ìwà ọ̀daràn mìíràn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nígbà tí wọ́n tún tẹnu mọ́ ṣíṣe àgbékalè ọlọ́pàá…

A Fún Ìjọba Àpapọ̀ Ní Gbèdéke Ọjọ́ Mẹ́rínlá Láti Yanjú Àdéhùn Tó Wà Láàrin Wà, Láìjẹ́ Bẹ́ẹ̀, A Ó…

Adarí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà,NLC àti TUC ti fún ìjọba àpapọ̀ ní gbèdéke ọjọ́ mẹ́rínlá láti yanjú àdéhùn tó wà láàrin wọnbẹ̀rẹ̀ láti ọ̀la , ìyẹn ọjọ́ kẹsàn án osù Kejì tí a wà yii.láìjẹ́ àwọn yóò gùnlè ètò ìyansẹ́lódì…

Ìbúgbàmù Ọjọ́ Kẹrìndínlógún: Gómìnà Gba Èsì Àyẹ̀wò Ohun Tó Ṣokùnfa Ìṣẹ̀lẹ̀

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti gba esi àyẹ̀wò ohun tó ṣokùnfa ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù tó wáyé ni agbègbè Bódìjà ni ìlú Ìbàdàn. Èsì àyẹ̀wò náà ni àwon ikọ̀ onímọ̀ ìṣegùn òyìnbó, ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò àti àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ni wọn gbé wá fún…
button