Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti tún fi ìdúróṣinṣin ìjọba rẹ̀ hàn láti kojú ìwà ipá àti àwọn ìpèníjà ààbò mìíràn tó ń halẹ̀ mọ́ ìdúróṣinṣin Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó sì tún fi hàn wi pé orílẹ̀-èdè yìí yóò borí àwọn oniṣẹ ibi tó ń wá ọ̀nà láti ba àlàáfíà àti ìṣọ̀kan rẹ̀ jẹ́ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.
Ààrẹ fi ìdánilójú naa hàn nígbà tó ń gbàlejò àwọn ọmọ ogun àti àwọn ilé iṣẹ́ ààbò mìíràn níbi ìfàájì ẹ̀sìn (ìfàájì ààwẹ̀) tí wọ́n ṣe ní Ilé Ìgbìmọ̀ ní Abuja.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí ìkọlù àwọn oníjàǹbá láìpẹ́ yìí sí àwùjọ Ngoshe ní ìjọba ìbílẹ̀ Gwoza ni Ìpínlẹ̀ Borno, Ààrẹ Tinubu fi ìgbẹ́kẹ̀lé hàn wi pé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò borí àwọn ìpèníjà ààbò tó ń dojúkọ orílẹ̀-èdè yìí Lai pẹ.
Olórí ẹgbẹ́ ọmọ ologun tún fi ìmoore hàn sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún atìlẹ́yìn wọn fún àwọn ọmọ ologun nínú ìjà tó ń lọ lọ́wọ́ lòdì sí àìní ààbò.